Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 23:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Olúwa Ọlọ́run yín fúnrarẹ̀ yóò lé wọn jáde kúrò ní ọ̀nà yín, yóò sì tì wọ́n jáde ní iwájú yín, ẹ̀yin yóò sì gba ilẹ̀ ìní wọn, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 OLUWA Ọlọrun yín yóo máa tì wọ́n sẹ́yìn fun yín, yóo máa lé wọn kúrò níwájú yín, ẹ óo sì gba ilẹ̀ wọn bí OLUWA Ọlọrun yín ti ṣèlérí fun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 OLUWA Ọlọrun nyin, on ni yio tì wọn jade kuro niwaju nyin, yio si lé wọn kuro li oju nyin; ẹnyin o si ní ilẹ wọn, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 23:5
9 Iomraidhean Croise  

“Kíyèsi èmi rán angẹli kan lọ ní iwájú rẹ, láti ṣọ́ ọ ni ọ̀nà àti láti mú ọ dé ibi ti mo ti pèsè sílẹ̀ fún.


Èmi yóò rán angẹli ṣáájú yín, èmi yóò sì lé àwọn Kenaani, àwọn ará Amori, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde.


Ṣe ohun tí èmi pàṣẹ fún ọ lónìí. Èmi lé àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde níwájú rẹ.


Olúwa yóò sì lé gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí kúrò níwájú u yín. Ẹ ó sì gba orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì tóbi jù yín lọ.


“Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbègbè òkè, láti Lebanoni sí Misrefoti-Maimu, àní, gbogbo àwọn ará Sidoni, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Israẹli. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ,


Èmi kì yóò lé ọ̀kankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí Joṣua fi sílẹ̀ nígbà tí ó kú jáde.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan