Joṣua 23:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní2 Ó sì pe gbogbo Israẹli jọ: àgbàgbà wọn, olórí wọn, adájọ́ àti àwọn ìjòyè, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti pọ̀ ní ọdún èmi ti di arúgbó. Faic an caibideilYoruba Bible2 ó bá pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, àwọn àgbààgbà, ati àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso, ó wí fún wọn pé, “Mo ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí mi; Faic an caibideilBibeli Mimọ2 Joṣua si pè gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn, o si wi fun wọn pe, Emi di arugbó tán, emi si pọ̀ li ọjọ́: Faic an caibideil |
Dafidi pe gbogbo àwọn oníṣẹ́ ti Israẹli láti péjọ ní Jerusalẹmu: Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà, àwọn alákòóso ìpín nínú iṣẹ́ bí ọba, àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí bíbojútó gbogbo àwọn ẹrù àti ohun ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ààfin àwọn oníṣẹ́ ààfin, àwọn ọkùnrin alágbára àti gbogbo àwọn ògbójú jagunjagun lápapọ̀.