Joṣua 23:12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní12 “Ṣùgbọ́n bí ẹ bá yí padà, tí ẹ sì gba ìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ́kù lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù láàrín yín, tí ẹ sì ń fọmọ fún ara yín ní ìyàwó, tí ẹ sì bá wọn ní àjọṣepọ̀, Faic an caibideilYoruba Bible12 Nítorí pé, bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ṣẹ́kù láàrin yín, tí ẹ̀ ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn, tí àwọn náà sì ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ yín, Faic an caibideilBibeli Mimọ12 Ṣugbọn bi ẹ ba daṣà ati pada, ti ẹ si faramọ́ iyokù awọn orile-ède wọnyi, ani awọn wọnyi ti o kù lãrin nyin, ti ẹ si bá wọn gbeyawo, ti ẹ si nwọle tọ̀ wọn, ti awọn si nwọle tọ̀ nyin: Faic an caibideil |
Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárín àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàrín gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di dandan fún ọ láti lọ sí àárín àwọn Filistini aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó?” Ṣùgbọ́n Samsoni wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ sí i púpọ̀púpọ̀.”