Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 23:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ọ̀kan nínú yín lé ẹgbẹ̀rún ọ̀tá, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín jà fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ninu yín ni ó ń bá ẹgbẹrun eniyan jà, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Ọkunrin kan ninu nyin yio lé ẹgbẹrun: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li ẹniti njà fun nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 23:10
27 Iomraidhean Croise  

Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní: Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn Balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà.


Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hagari lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí tiwọn ké pe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.


Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbèkùn.


Olúwa, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí; kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!


Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa, Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.


Olúwa yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.”


Ẹgbẹ̀rún yóò sá nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan; nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún gbogbo yín lẹ ó sálọ, títí a ó fi yín sílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè, gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.”


Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀tá yín: wọn yóò sì tipa idà kú.


Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa ṣẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn: Àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá: Àwọn ọ̀tá yín yóò tipa idà kú níwájú yín.


Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dafidi; ilé Dafidi yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí angẹli Olúwa níwájú wọn.


Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa?


yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Israẹli, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀tá rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi ààyè fún ìjayà níwájú u wọn.


Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.”


Olúwa yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.


Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, Olúwa Ọlọ́run yín tìkára rẹ̀ ni yóò jà fún un yín.”


Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn, èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí; nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí, àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn.


Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún, tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbàárùn-ún sá, bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n, bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?


Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí àti ilẹ̀ wọn ní Joṣua ṣẹ́gun ní ìwọ́de ogun ẹ̀ẹ̀kan, nítorí tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, jà fún Israẹli.


Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣọ́ra gidigidi láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín.


Ẹ̀yin tìkára yín sì ti rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí nítorí yín, Olúwa Ọlọ́run yín ni ó jà fún yín.


Nígbà tí ó rí egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tuntun kan, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin.


Lẹ́yìn Ehudu, ni Ṣamgari ọmọ Anati ẹni tí ó pa ọgọ́rùn-ún mẹ́fà Filistini pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Israẹli kúrò nínú ìpọ́njú.


Jonatani sì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ìlú olódi àwọn aláìkọlà yìí. Bóyá Olúwa yóò jà fún wa, kò sí ohun tó lè di Olúwa lọ́wọ́ láti gbàlà, yálà nípasẹ̀ púpọ̀ tàbí nípasẹ̀ díẹ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan