Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 21:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Wọ́n fún wọn ní Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni), pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù tí ó yí wọn ká, ní ilẹ̀ òkè Juda. (Arba ni baba ńlá Anaki.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Àwọn ni wọ́n fún ní Kiriati Ariba tí wọ́n ń pè ní ìlú Heburoni lónìí, (Ariba yìí ni baba Anaki), ati àwọn pápá ìdaran tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ ní agbègbè olókè ti Juda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Nwọn si fi Kiriati-arba, ti iṣe Hebroni fun wọn, (Arba ni baba Anaki ni ilẹ òke Juda,) pẹlu àgbegbe rẹ̀ yi i kakiri.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 21:11
15 Iomraidhean Croise  

ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara.


Jakọbu sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni Mamre ní tòsí i Kiriati-Arba (Hebroni). Níbi tí Abrahamu àti Isaaki gbé.


Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Absalomu sì wí fún ọba pé, “Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa, ní Hebroni.


A fún wọn ní Hebroni ní Juda pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.


Ní àkókò náà ni Maria sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Judea;


(Hebroni a sì máa jẹ́ Kiriati-Arba ní ẹ̀yìn Arba, èyí tí ó jẹ́ ènìyàn ńlá nínú àwọn ọmọ Anaki.) Nígbà náà ni ilẹ̀ náà sinmi ogun.


Hamuta, Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) àti Ṣiori: ìlú mẹ́sàn-án àti àwọn ìletò rẹ̀


(Ìlú wọ̀nyí ni a fún àwọn ọmọ Aaroni tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Kohati tí í ṣe ọmọ Lefi, nítorí tí ìpín àkọ́kọ́ jẹ́ tiwọn).


Ṣùgbọ́n àwọn oko àti àwọn abúlé ní agbègbè ìlú náà ni wọ́n ti fi fún Kalebu ọmọ Jefunne gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀.


Ogun Juda sì tún ṣígun tọ ará Kenaani tí ń gbé Hebroni (tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiriati-Arba) ó sì ṣẹ́gun Ṣeṣai, Ahimani àti Talmai.


Àti àwọn tí ó wà ni Hebroni, àti sí gbogbo àwọn ìlú ti Dafidi tìkára rẹ̀ àti tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa ń rìn ká.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan