Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 20:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan Kedeṣi ní Galili ní ìlú òkè Naftali, Ṣekemu ní ìlú òkè Efraimu, àti Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) ní ìlú òkè Juda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Wọ́n ya Kedeṣi sọ́tọ̀ ní Galili ní agbègbè olókè ti Nafutali, ati Ṣekemu ní agbègbè olókè ti Efuraimu, ati Kiriati Ariba (tí wọ́n ń pè ní Heburoni), ní agbègbè olókè ti Juda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Nwọn si yàn Kedeṣi ni Galili ni ilẹ òke Naftali, ati Ṣekemu ni ilẹ òke Efraimu, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni) ni ilẹ òke Juda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 20:7
22 Iomraidhean Croise  

Wọ́n fún wọn ní Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni), pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù tí ó yí wọn ká, ní ilẹ̀ òkè Juda. (Arba ni baba ńlá Anaki.)


Ní àkókò náà ni Maria sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Judea;


Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.


Láti ara ẹ̀yà Naftali ni a ti fún wọn ní: Kedeṣi ní Galili (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Hamoti Dori àti Karitani, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́ta.


Ní ilẹ̀ òkè Efraimu wọ́n fún wọn ní: Ṣekemu (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn) àti Geseri,


Ní àfikún wọ́n sì fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ní Hebroni (ọ̀kan nínú ìlú ààbò fún àwọn apànìyàn) pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù rẹ̀, Libina,


(Hebroni a sì máa jẹ́ Kiriati-Arba ní ẹ̀yìn Arba, èyí tí ó jẹ́ ènìyàn ńlá nínú àwọn ọmọ Anaki.) Nígbà náà ni ilẹ̀ náà sinmi ogun.


Rehoboamu sì lọ sí Ṣekemu nítorí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi jẹ ọba.


ó sì kú ní Kiriati-Arba (ìyẹn ní Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu lọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti sọkún nítorí Sara.


“Mẹ́fà lára ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ ìlú ibi ìsásí, tí ẹni tí ó bá pa ènìyàn yóò sá sí. Ní àfikún, ẹ fún wọn ní méjìlélógójì (42) ìlú sí i.


Mose sì ya àwọn ìlú mẹ́ta kan sọ́tọ̀ ní apá ìwọ̀-oòrùn Jordani.


nítorí tí ìwọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo òfin yìí tí mo pàṣẹ fún ọ lónìí yìí, kí o fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì rìn ní ọ̀nà an rẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, kí o ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀.


Ọba Kedeṣi ọ̀kan ọba Jokneamu ni Karmeli ọ̀kan


Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani ti Jeriko, wọ́n ya Beseri ní aginjù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀yà Reubeni, Ramoti ní Gileadi ní ẹ̀yà Gadi, àti Golani ní Baṣani ní ẹ̀yà Manase.


Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Joṣua, ó fi ìpín fún Kalebu ọmọ Jefunne, ìpín ní Juda—Kiriati-Arba, tí í ṣe Hebroni. (Arba sì ní baba ńlá Anaki.)


Àwọn ìlú olódi sì Siddimu, Seri, Hamati, Rakàti, Kinnereti,


Kedeṣi, Edrei, Eni-Aṣọri,


Nígbà náà ni Joṣua pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli jọ ní Ṣekemu. Ó pe àwọn àgbàgbà, àwọn olórí, onídàájọ́ àti àwọn ìjòyè Israẹli, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run.


Ní ọjọ́ kan Abimeleki ọmọ Jerubbaali lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ ní Ṣekemu ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ àti gbogbo àwọn ìbátan ìyá rẹ̀ wí pé,


Rehoboamu sì lọ sí Ṣekemu, nítorí gbogbo Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi í jẹ ọba.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan