Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 20:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Nígbà tí ó bá sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, yóò sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àtiwọ ibodè ìlú, kí ó sì ṣe àlàyé ara rẹ̀ ní iwájú àwọn àgbàgbà ìlú náà. Nígbà náà ni wọn yóò gbà á sí ìlú wọn, wọn yóò sì fun ní ibùgbé láàrín wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan sá lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọ̀hún, kí ó dúró ní ẹnubodè ìlú, kí ó sì ro ẹjọ́ fún àwọn àgbààgbà ibẹ̀. Wọn yóo mú un wọ inú ìlú lọ, wọn yóo fún un ní ibi tí yóo máa gbé, yóo sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 On o si salọ si ọkan ninu ilu wọnni, yio si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na, yio si rò ẹjọ́ rẹ̀ li etí awọn àgba ilu na, nwọn o si gbà a sọdọ sinu ilu na, nwọn o si fun u ni ibi kan, ki o le ma bá wọn gbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 20:4
8 Iomraidhean Croise  

“Nígbà tí mo jáde la àárín ìlú lọ sí ẹnu ibodè, nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro,


Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu, a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè, bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan.


Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,


A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú


Ṣùgbọ́n, Ebedimeleki, ará Kuṣi ìjòyè nínú ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremiah sínú kànga. Nígbà tí ọba jókòó ní ẹnu-bodè Benjamini.


Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú ṣinṣin:


kí ẹni tí ó bá ṣèèṣì pa ènìyàn tàbí tí ó bá pa ènìyàn láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ lè sálọ sí ibẹ̀, fún ààbò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan