Joṣua 2:11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní11 Bí a ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ọkàn wa pami kò sì sí okun kankan fún wa mọ́ nítorí i yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ní ayé. Faic an caibideilYoruba Bible11 Bí a ti gbọ́ ni jìnnìjìnnì ti bò wá, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn sì ti bá gbogbo eniyan nítorí yín, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun ọ̀run ati ayé. Faic an caibideilBibeli Mimọ11 Lọgán bi awa ti gbọ́ nkan wọnyi, àiya wa já, bẹ̃ni kò si sí agbara kan ninu ọkunrin kan mọ́ nitori nyin; nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li Ọlọrun loke ọrun, ati nisalẹ aiye. Faic an caibideil |