Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 18:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli péjọ ní Ṣilo, wọ́n si kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ibẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun ilẹ̀ náà, gbogbo wọn péjọ sí Ṣilo, wọ́n sì pa àgọ́ àjọ níbẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si pejọ ni Ṣilo, nwọn si gbé agọ́ ajọ ró nibẹ̀: a si ṣẹgun ilẹ na niwaju wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 18:1
26 Iomraidhean Croise  

Nítorí pé, èmi kò ì ti gbé inú ilé kan láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ọmọ Israẹli gòkè ti ilẹ̀ Ejibiti wá, títí di òní yìí, ṣùgbọ́n èmi ti ń rìn nínú àgọ́, fún ibùgbé mi.


Jeroboamu sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́n ní aya Jeroboamu. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣilo. Ahijah wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn yìí.


Bẹ́ẹ̀ ni aya Jeroboamu sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Ahijah ní Ṣilo. Ahijah kò sì ríran; ojú rẹ̀ ti fọ́ nítorí ogbó rẹ̀.


Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni yọ Abiatari kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà Olúwa, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípa ilé Eli ní Ṣilo ṣẹ.


Àwọn ọkùnrin wọn wọ inú rẹ̀, wọ́n sì gbà ilẹ̀ náà. Ìwọ sì tẹ orí àwọn ará a Kenaani, tí ń gbé inú ilẹ̀ náà ba níwájú wọn; ó fi àwọn ará a Kenaani lé wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọba wọn àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kí wọn ṣe wọn bí ó ti wù wọ́n.


Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀, àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.


Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà; ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé.


nígbà náà ni èmi yóò ṣe ilé yìí bí Ṣilo, èmi yóò sì ṣe ìlú yìí ní ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ ”


Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa pé, ilé yìí yóò dàbí Ṣilo, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremiah nínú ilé Olúwa.


Àwọn ọgọ́rin ọkùnrin wá láti Ṣekemu, Ṣilo àti Samaria, wọ́n fa irùngbọ̀n wọn, wọ́n ya aṣọ wọn, wọ́n ṣá ara wọn lọ́gbẹ́, wọ́n mú ẹbọ ọpẹ́ àti tùràrí wá sí ilé Olúwa.


Tí a ó sì fi ṣe ilẹ̀ náà níwájú Olúwa; ẹ̀yin lè padà tí yóò sì di òmìnira lọ́wọ́ ìdè níwájú Olúwa àti Israẹli. Ilẹ̀ yìí yóò sì jẹ́ tiyín níwájú Olúwa.


Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Joṣua wá sí ilẹ̀ ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókò Dafidi.


ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Israẹli tí kò tí ì gba ogún ìní wọn.


Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Joṣua pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà káàkiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀. Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, kí èmi kí ò lè ṣẹ́ kèké fún yin ní ibí ní Ṣilo ní iwájú Olúwa.”


Wọ̀nyí ni àwọn ilẹ̀ tí Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti àwọn olórí ẹ̀yà agbo ilé Israẹli fi ìbò pín ní Ṣilo ní iwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Báyìí ni wọ́n parí pínpín ilẹ̀ náà.


Ní Ṣilo, ní Kenaani, wọn sọ fún wọn pé, “Olúwa pàṣẹ nípasẹ̀ Mose pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa.”


gbogbo àjọ Israẹli péjọ ní Ṣilo láti lọ bá wọn jagun.


Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní Olúwa, ní ibi tí àgọ́ Olúwa dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa.


Báyìí ni àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ará Israẹli sílẹ̀ ní Ṣilo ní Kenaani láti padà sí Gileadi, ilẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose wá.


Wọ́n tẹ̀síwájú láti lo àwọn ère tí Mika ṣe, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọ́run wà ní Ṣilo.


Wọ́n rí àwọn irínwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi Gileadi, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣilo àwọn ará Kenaani.


Wọ́n sì wí pé, “Kíyèsi i ayẹyẹ ọlọ́dọọdún fún Olúwa wà ní Ṣilo ní ìhà àríwá Beteli àti ìhà ìlà-oòrùn òpópó náà tí ó gba Beteli kọjá sí Ṣekemu, àti sí ìhà gúúsù Lébónà.”


Nígbà tí ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó sì mú un gòkè lọ pẹ̀lú ara rẹ̀. Pẹ̀lú ẹgbọrọ màlúù mẹ́ta, àti ìyẹ̀fun efa kan, àti ìgò ọtí wáìnì kan, ó sì mú un wá sí ilé Olúwa ní Ṣilo: ọmọ náà sì wà ní ọmọdé.


Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ ní Ṣilo, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì, Hofini àti Finehasi ti jẹ́ àlùfáà Olúwa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan