Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 17:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nítorí náà ìpín yìí wà fún ìyókù àwọn ènìyàn Manase: ní agbo ilé Abieseri, Heleki, Asrieli, Ṣekemu, Heferi àti Ṣemida. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọmọ ọkùnrin Manase ọmọ Josẹfu ní agbo ilé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Wọ́n fún àwọn ìdílé Manase yòókù ní ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn: àwọn bíi Abieseri, Heleki, Asirieli, Ṣekemu, Heferi, ati Ṣemida. Àwọn ni ọmọkunrin Manase, tíí ṣe ọmọ Josẹfu; wọ́n sì jẹ́ olórí fún àwọn ìdílé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Awọn ọmọ Manasse iyokù si ní ilẹ-iní gẹgẹ bi idile wọn; awọn ọmọ Abieseri, ati awọn ọmọ Heleki, ati awọn ọmọ Asrieli, ati awọn ọmọ Ṣekemu, ati awọn ọmọ Heferi, ati awọn ọmọ Ṣemida: awọn wọnyi ni awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 17:2
6 Iomraidhean Croise  

Arábìnrin rẹ̀. Hamoleketi bí Iṣhodi, Abieseri àti Mahila.


Èyí ní ìpín ẹ̀yà Manase tí í ṣe àkọ́bí Josẹfu, fún Makiri, àkọ́bí Manase. Makiri sì ni baba ńlá àwọn ọmọ Gileadi, tí ó ti gba Gileadi àti Baṣani nítorí pé àwọn ọmọ Makiri jẹ́ jagunjagun ńlá.


Nísinsin yìí Ṣelofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkùnrin, bí kò ṣe àwọn ọmọbìnrin, tí orúkọ wọn jẹ́: Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa.


Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù ofira èyí ti ṣe ti Joaṣi ará Abieseri, níbi tí Gideoni ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọntí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Midiani.


Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Àṣeyọrí wo ni mo ti ṣe tí ó tó fiwé tiyín? Àṣàkù àjàrà Efraimu kò ha dára ju gbogbo ìkórè àjàrà Abieseri lọ bí?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan