Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 16:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ó tún mú àwọn ìlú àti ìletò wọn tí ó yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Efraimu tí ó wà ní àárín ìní àwọn ọmọ Manase.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọn tí ó wà ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Manase, ṣugbọn tí a fi fún ẹ̀yà Efuraimu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Pẹlu ilu ti a yàsọtọ fun awọn ọmọ Efraimu lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Manasse, gbogbo ilu na pẹlu ileto wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 16:9
6 Iomraidhean Croise  

Ó sì fi jẹ ọba lórí Gileadi Aṣuri àti Jesreeli àti lórí Efraimu àti lórí Benjamini àti lórí gbogbo Israẹli.


Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Beteli àti àwọn ìletò tí ó yíká, Narani lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, Geseri àti àwọn ìletò rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣekemu àti àwọn ìletò rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Ayahi àti àwọn ìletò.


Efraimu yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Manase láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.


Wọn kò lé àwọn ara Kenaani tí ń gbé ni Geseri kúrò, títí di òní yìí ni àwọn ará Kenaani ń gbé láàrín àwọn ènìyàn Efraimu, Ṣùgbọ́n wọ́n mú wọ́n sìn.


Láti Tapua ààlà náà sì lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, ní Kana-Rafini, ó sì parí ní Òkun. Èyí ni ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Efraimu, ní agbo ilé agbo ilé.


Ààlà rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ odò Kana, ní ìhà gúúsù odò náà. Àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti Efraimu wà ní àárín àwọn ìlú Manase, ṣùgbọ́n ààlà Manase ni ìhà àríwá odò náà, ó sì yọ sí Òkun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan