Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 16:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Báyìí ni Manase àti Efraimu, àwọn ọmọ Josẹfu, gba ilẹ̀ ìní wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Josẹfu, tí à ń pè ní ẹ̀yà Manase ati ẹ̀yà Efuraimu ṣe gba ìpín tiwọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Bẹ̃li awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu, gbà ilẹ-iní wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 16:4
6 Iomraidhean Croise  

Ó sì sọ orúkọ èkejì ní Efraimu, ó sì wí pé, “Nítorí pé Ọlọ́run fún mi ní ọmọ ní ilẹ̀ ìpọ́njú mi.”


Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárín àwọn ẹ̀yà méjìlá Israẹli, pẹ̀lú ìpín méjì fún Josẹfu.


Àwọn ọmọ Josẹfu sì di ẹ̀yà méjì, Manase àti Efraimu. Àwọn ọmọ Lefi kò gba ìpín ní ilẹ̀ náà bí kò ṣe àwọn ìlú tí wọn yóò máa gbé, pẹ̀lú pápá oko tútù fún ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran wọn.


Èyí ni ilẹ̀ Efraimu, ní agbo ilé agbo ilé: Ààlà ìní wọn lọ láti Atarotu-Addari ní ìlà-oòrùn lọ sí Òkè Beti-Horoni.


Àwọn ọmọ Josẹfu sì wí fún Joṣua pé, “Èéṣe tí ìwọ fi fún wa ní ìpín ilẹ̀ kan àti ìdákan ní ìní? Nítorí àwa jẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí Olúwa ti bùkún lọ́pọ̀lọpọ̀.”


Ẹ̀yin yóò sì pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje kí Juda dúró sí ilẹ̀ rẹ̀ ni ìhà gúúsù àti ilé Josẹfu ní ilẹ̀ rẹ̀ ní ìhà àríwá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan