Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 16:2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ó sì tẹ̀síwájú láti Beteli (tí í ṣe Lusi) kọjá lọ sí agbègbè àwọn ará Arki ní Atarotu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Láti Bẹtẹli, ó lọ sí Lusi, ó sì kọjá lọ sí Atarotu, níbi tí àwọn ọmọ Ariki ń gbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 O si ti Beti-eli yọ si Lusi, o si kọja lọ si àgbegbe Arki dé Atarotu;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 16:2
8 Iomraidhean Croise  

Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Beteli (Ilé Ọlọ́run) bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lusi tẹ́lẹ̀ rí.


Ó sì ṣe, Dafidi dé orí òkè, níbi tí ó gbé wólẹ̀ sin Ọlọ́run, sì wò ó, Huṣai ará Arki sì wá láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ yíya, àti erùpẹ̀, lórí rẹ̀.


Huṣai ọ̀rẹ́ Dafidi sì wá sí ìlú, Absalomu sì wá sí Jerusalẹmu.


Ó sì ṣe, nígbà tí Huṣai ará Arki, ọ̀rẹ́ Dafidi tọ Absalomu wá, Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Kí ọba ó pẹ́! Kí ọba ó pẹ́.”


Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn ọba. Huṣai ará Arki jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba.


Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Beteli àti àwọn ìletò tí ó yíká, Narani lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, Geseri àti àwọn ìletò rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣekemu àti àwọn ìletò rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Ayahi àti àwọn ìletò.


Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúúsù ní ọ̀nà Lusi, (èyí ni Beteli) ó sì dé Atarotu-Addari, ní orí òkè tí ó wà ní gúúsù Beti-Horoni


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan