Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 15:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Nefitoa, ó sì jáde sí ìlú Òkè Efroni, ó sì lọ sí apá ìsàlẹ̀ Baalahi, (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Láti ibẹ̀, ó tún bẹ̀rẹ̀ láti orí òkè títí dé odò Nefitoa, ó lọ sí apá ibi tí àwọn ìlú ńláńlá wà lẹ́bàá òkè Efuroni, ó wá pada sí apá Baala (tí a tún ń pè ní Kiriati Jearimu.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 A si fà àla na lati ori òke lọ si isun omi Neftoa, o si nà lọ si ilu òke Efroni; a si fà àla na lọ si Baala, (ti iṣe Kirjati-jearimu:)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 15:9
8 Iomraidhean Croise  

Dafidi sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Baalahi ní Juda wá, láti mú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrín àwọn kérúbù.


Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Baalahi ti Juda (Kiriati-Jearimu) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Olúwa tí a fi orúkọ rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrín kérúbù—gòkè wá.


Kiriati-Baali (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu) àti Rabba ìlú méjì àti ìletò wọn.


Ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun Kiriati-Jearimu ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi Nefitoa.


Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọmọ Israẹli jáde, wọ́n sì dé ìlú wọn ní ọjọ́ kẹta: Gibeoni, Kefira, Beeroti àti Kiriati-Jearimu.


Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kiriati-Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀-oòrùn Kiriati-Jearimu ni Mahane-Dani títí di òní yìí.


Nígbà náà, wọ́n rán àwọn ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí Kiriati-Jearimu wí pé, “àwọn Filistini ti dá àpótí ẹ̀rí Olúwa padà. Ẹ sọ̀kalẹ̀ wá, kí ẹ gbé e gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ yín.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan