Joṣua 15:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní8 Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí Àfonífojì Beni-Hinnomu ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúúsù ti Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu). Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí Àfonífojì Hinnomu tí ń bẹ ní ìpẹ̀kun Àfonífojì Refaimu ní ìhà àríwá. Faic an caibideilYoruba Bible8 Ààlà náà tún lọ sí apá òkè, sí àfonífojì ọmọ Hinomu ní apá gúsù òkè àwọn ará Jebusi (tíí ṣe ìlú Jerusalẹmu). Ó tún lọ títí dé orí òkè náà, tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, ní apá ìwọ̀ oòrùn, ní òpin ìhà àríwá àfonífojì Refaimu. Faic an caibideilBibeli Mimọ8 Àla na si gòke lọ si ìha afonifoji ọmọ Hinnomu si ìha gusù ti Jebusi (ti iṣe Jerusalemu): àla na si gòke lọ si ori òke nla ti mbẹ niwaju afonifoji Hinnomu ni ìha ìwọ-õrùn, ti mbẹ ni ipẹkun afonifoji Refaimu ni ìha ariwa: Faic an caibideil |