Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 15:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ààlà náà gòkè lọ títí dé Debiri láti Àfonífojì Akori, ó sì yípadà sí àríwá Gilgali, èyí tí ń bẹ ní iwájú òkè Adummimu, tí ń bẹ ní ìhà gúúsù odò náà. Ó sì tẹ̀síwájú sí apá omi En-Ṣemeṣi, ó sì jáde sí En-Rogeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Ó lọ láti àfonífojì Akori títí dé Debiri, ó wá yípo lọ sí apá ìhà àríwá, lọ sí Giligali, tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, tí ó wà ní apá gúsù àfonífojì náà. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ibi odò Enṣemeṣi, ó sì pin sí Enrogeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Àla na si gòke lọ si Debiri lati afonifoji Akoru, ati bẹ̃ lọ si ìha ariwa, ti o dojukọ Gilgali, ti mbẹ niwaju òke Adummimu, ti mbẹ ni ìha gusù odò na: àla si kọja si apa omi Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Eni-rogeli:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 15:7
13 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Adonijah fi àgùntàn àti màlúù àti ẹran ọ̀sìn tí ó sanra rú ẹbọ níbi òkúta Soheleti tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ En-Rogeli. Ó sì pe gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ ọba, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Juda tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ ọba.


Jonatani àti Ahimasi sì dúró ní En-Rogeli ọ̀dọ́mọdébìnrin kan sì lọ, ó sì sọ fún wọn, wọ́n sì lọ wọ́n sọ fún Dafidi ọba nítorí pé kí a má bá à rí wọn pé wọ́n wọ ìlú.


Wọ́n sì kó òkìtì òkúta ńlá lé Akani lórí títí di òní yìí. Nígbà náà ní Olúwa sì yí ìbínú gbígbóná rẹ̀ padà. Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Àfonífojì Akori láti ìgbà náà.


Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè, ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú. Ó wí pé, ‘èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn, tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi, ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi, òróró mi àti ohun mímu mi.’


Ṣaroni yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran, àti Àfonífojì Akori yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran, fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi.


Ó sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí).


Nígbà náà ni Joṣua padà sí ibùdó ní Gilgali pẹ̀lú gbogbo Israẹli.


Nígbà náà ni Joṣua pẹ̀lú gbogbo Israẹli, mú Akani ọmọ Sera, fàdákà, ẹ̀wù àti wúrà tí a dà, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àgùntàn àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ni, wọ́n sì kó wọn lọ sí ibi Àfonífojì Akori.


Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìn-ín-ní àwọn ènìyàn náà lọ láti Jordani, wọ́n sì dúró ní Gilgali ní ìlà-oòrùn Jeriko.


ààlà náà sì tún dé Beti-Hogla, ó sì lọ sí ìhà àríwá Beti-Araba. Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bohani ti ọmọ Reubeni.


Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni-Ṣemeṣi, ó tẹ̀síwájú dé Geliloti tí ó kọjú sí òkè Adummimu, ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Òkúta Bohani ọmọ Reubeni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan