Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 15:4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ó tún kọjá lọ sí Asmoni, ó sì papọ̀ mọ́ Wadi ti Ejibiti, ó parí sí Òkun. Èyí ni ààlà wọn ní ìhà gúúsù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Lẹ́yìn náà, ó lọ títí dé Asimoni, ó tọ ipa odò Ijipti, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Òun ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ Juda ní apá ìhà gúsù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Lati ibẹ̀ o lọ dé Asmoni, o si nà lọ si odò Egipti; opín ilẹ na si yọ si okun: eyi ni yio jẹ́ àla ni gusù nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 15:4
8 Iomraidhean Croise  

Ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate:


Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe àpéjọ nígbà náà, àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńláńlá ni, láti ìwọ Hamati títí dé odò Ejibiti. Wọ́n sì ṣàjọyọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ọjọ́ méje àti ọjọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀.


“Èmi yóò fi ìdí òpin ààlà ilẹ̀ rẹ lélẹ̀ láti etí Òkun pupa títí dé Òkun àwọn ara Filistini, láti aṣálẹ̀ títí dé etí odò Eufurate: Èmi yóò fa àwọn ènìyàn ti ń gbé ilẹ̀ náà lé ọ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ.


Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.


Kí òpin ilẹ̀ rẹ̀ kí ó sì yíká láti Asmoni lọ dé odò Ejibiti, Òkun ni yóò sì jẹ òpin rẹ.


láti odò Ṣihori ní ìlà-oòrùn Ejibiti sí agbègbè Ekroni ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kenaani (agbègbè ìjòyè Filistini márùn-ún ní Gasa, Aṣdodu, Aṣkeloni, Gitti àti Ekroni; ti àwọn ará Affimu);


Ó sì gba gúúsù Akrabbimu lọ, títí dé Sini àti sí iwájú ìhà gúúsù Kadeṣi-Barnea. Nígbà náà ó sì tún kọjá Hesroni lọ sí Adari, ó sì tún yípo yíká lọ sí Karka.


Aṣdodu, agbègbè ìlú rẹ̀ àti ìletò; àti Gasa, ìlú rẹ̀ àti ìletò, títí ó fi dé odò Ejibiti àti agbègbè Òkun ńlá (Òkun Mẹditarenia).


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan