Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 13:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Àti ilẹ̀ àwọn ará Gebali; àti gbogbo àwọn Lebanoni dé ìlà-oòrùn, láti Baali-Gadi ní ìsàlẹ̀ Òkè Hermoni dé Lebo-Hamati.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 ati ilẹ̀ àwọn ará Gebali, gbogbo Lẹbanoni ní apá ìlà oòrùn, láti Baaligadi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni títí dé ibodè Hamati.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ati ilẹ awọn Gebali, ati gbogbo Lebanoni ni ìha ìla-õrùn, lati Baali-gadi nisalẹ òke Hermoni titi o fi dé atiwọ̀ Hamati:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 13:5
14 Iomraidhean Croise  

Àwọn oníṣọ̀nà Solomoni àti Hiramu àti àwọn òṣìṣẹ́ láti Gebali sì gbẹ́ wọn, wọ́n sì pèsè igi àti òkúta láti fi kọ́ ilé náà.


Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe àpéjọ nígbà náà, àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńláńlá ni, láti ìwọ Hamati títí dé odò Ejibiti. Wọ́n sì ṣàjọyọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ọjọ́ méje àti ọjọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀.


Gebali, Ammoni àti Amaleki, Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.


‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi? Hamati kò ha dàbí i Arpadi, àti Samaria bí i Damasku?


Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn. Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.


Àwọn àgbàgbà Gebali, àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀, wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ, gbogbo ọkọ̀ ojú Òkun àti àwọn atukọ̀ Òkun wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.


Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì. Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ? Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí?


Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti Aginjù Sini títí dé Rehobu lọ́nà Lebo-Hamati.


Àti láti orí òkè Hori sí Lebo-Hamati. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Ṣedadi,


Ẹ yípadà kí ẹ sì tẹ̀síwájú ní ìrìnàjò yín lọ sí ilẹ̀ òkè àwọn ará Amori: Ẹ tọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń gbé Arabah lọ ní aginjù, ní àwọn orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní gúúsù àti ní etí Òkun, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani àti lọ sí Lebanoni, títí fi dé odò ńlá Eufurate.


Jẹ́ kí n kọjá lọ wo ilẹ̀ rere ti ìkọjá Jordani: Ilẹ̀ òkè dídára nì àti Lebanoni.”


láti òkè Halaki títí dé òkè Seiri, sí Baali-Gadi ní Àfonífojì Lebanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Hermoni. Ó sì mú gbogbo ọba wọn, ó sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n.


sí àwọn ará Kenaani ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Amori, Hiti, Peresi àti Jebusi ní orí òkè; àti sí àwọn Hifi ní ìsàlẹ̀ Hermoni ní agbègbè Mispa.


Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani, láti Baali-Gadi ní Àfonífojì Lebanoni sí Òkè Halaki, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Seiri (Joṣua sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan