Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 13:16 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Láti agbègbè Aroeri ní etí Arnoni Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrín Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Medeba

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati gbogbo ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Àla wọn bẹ̀rẹ lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji nì, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ti mbẹ ni ìha Medeba;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 13:16
18 Iomraidhean Croise  

Wọ́n sì kọjá odò Jordani, wọ́n sì pàgọ́ ní Aroeri, ní ìhà apá ọ̀tún ìlú tí ó wà láàrín Àfonífojì Gadi, àti sí ìhà Jaseri.


Wọ́n gba iṣẹ́ ẹgbẹ̀rin méjìlélọ́gbọ̀n kẹ̀kẹ́ àti agun-kẹ̀kẹ́ àti ọba Maaka pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ tí ó wá pàgọ́ ní ẹ̀bá Medeba, nígbà tí àwọn ará Ammoni kójọpọ̀ láti ìlú wọn, tí wọ́n sì jáde lọ fún ogun.


Heṣboni àti Eleale ké sóde, ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi. Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.


Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni.


Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Aroeri níbi odò Arnoni, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gileadi pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn.


Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni. Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín Àfonífojì náà dé Odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi.


Èyí ni Mose fi fún ẹ̀yà Reubeni ni agbo ilé sí agbo ilé:


sí Heṣboni àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Diboni, Bamoti Baali, Beti-Baali-Mioni,


Ó sì lọ títí láti Aroeri tí ń bẹ létí Àfonífojì Arnoni, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárín Àfonífojì náà, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Medeba títí dé Diboni.


Mose ti fún àwọn ẹ̀yà méjì àti ààbọ̀ ní ogún wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi ni kò fi ìní fún ní àárín àwọn tí ó kù.


Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi kò ní ìpín ní àárín yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. Olúwa ni ìní wọ́n. Gadi, Reubeni àti ìdajì ẹ̀yà Manase, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani. Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.”


Fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300) ni Israẹli fi ṣe àtìpó ní Heṣboni, Aroeri àti àwọn ìgbèríko àti àwọn ìlú tí ó yí Arnoni ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà?


Àti sí àwọn tí ó wà ní Aroeri, àti sí àwọn tí ó wà ní Sifimoti, àti sí àwọn tí ó wà ni Eṣitemoa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan