Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:9 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Joṣua sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ: Ó sì já iṣan ẹ̀yìn ẹsẹ̀ ẹṣin wọn ó sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Joṣua ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí ó ṣe sí wọn: ó dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, ó sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn níná.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Joṣua si ṣe si wọn gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun u: o já patì ẹṣin wọn, o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:9
6 Iomraidhean Croise  

Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn, kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn, nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn, wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n.


Dafidi sì gba ẹgbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ẹlẹ́ṣin, àti ẹgbàáwàá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀: Dafidi sì já gbogbo àwọn ẹṣin kẹ̀kẹ́ wọn ní pàtì, ṣùgbọ́n ó dá ọgọ́ọ̀rún kẹ̀kẹ́ sí nínú wọn.


Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run. A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè A ó gbé mi ga ní ayé.


“Kíyèsi i èmi dojúkọ ọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín, idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run. Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé Ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni a kì yóò sì tún gbọ́ mọ́.”


Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí ní àkókò yìí ní ọ̀la, gbogbo wọn ni èmi yóò fi lé Israẹli lọ́wọ́ ní pípa. Ìwọ yóò já iṣan ẹ̀yìn ẹṣin wọn, ìwọ yóò sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan