Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Olúwa sì fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì lépa wọn ní gbogbo ọ̀nà títí dé Sidoni ńlá, sí Misrefoti-Maimu, àti sí Àfonífojì Mispa ní ìlà-oòrùn, títí tí kò fi ku ẹnìkankan sílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 OLUWA fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n. Wọ́n lé wọn títí dé Sidoni ati Misirefoti Maimu, ati apá ìlà oòrùn títí dé àfonífojì Misipa, wọ́n pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 OLUWA si fi wọn lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn, nwọn si lé wọn titi dé Sidoni nla ati titi dé Misrefoti-maimu, ati dé afonifoji Mispa ni ìha ìla-õrùn; nwọn si pa wọn tobẹ̃ ti kò kù ẹnikan silẹ fun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:8
13 Iomraidhean Croise  

Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀, àti Heti.


“Sebuluni yóò máa gbé ní etí Òkun, yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi, agbègbè rẹ yóò tàn ká títí dé Sidoni.


Wọ́n sì wá sí Gileadi, àti sí ilé Tatimi Hodṣi; wọ́n sì wá sí Dani Jaani àti yíkákiri sí Sidoni,


Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọ àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun, nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀: “Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”


Àti Hamati pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀ Tire àti Sidoni bí o tilẹ̀ ṣe ọlọ́gbọ́n gidigidi.


nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì ti fi wọ́n lé ẹ lọ́wọ́, tí ìwọ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ìwọ kí ó sì pa wọ́n run pátápátá. Má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣàánú fún wọn.


Ṣùgbọ́n kí ó dá a yín lójú lónìí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ń ṣáájú u yín lọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun. Yóò jó wọn run, yóò sì tẹ orí wọn ba níwájú yín. Ẹ̀yin yóò sì lé wọ́n jáde, ẹ̀yin yóò sì run wọ́n kíákíá, bí Olúwa ti ṣèlérí fún un yín.


Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ-ogun àwọn ọba márààrún run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn.


sí àwọn ará Kenaani ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Amori, Hiti, Peresi àti Jebusi ní orí òkè; àti sí àwọn Hifi ní ìsàlẹ̀ Hermoni ní agbègbè Mispa.


Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ yọ sí wọn ní òjijì ní ibi omi Meromu, wọ́n sì kọlù wọ́n,


“Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbègbè òkè, láti Lebanoni sí Misrefoti-Maimu, àní, gbogbo àwọn ará Sidoni, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Israẹli. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ,


Ó sì lọ sí Abdoni, Rehobu, Hammoni àti Kana títí dé Sidoni ńlá.


Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún baba ńlá wọn. Kò sì sí ọ̀kankan nínú àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè dojúkọ wọ́n. Olúwa sì fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn ní ọwọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan