Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí ní àkókò yìí ní ọ̀la, gbogbo wọn ni èmi yóò fi lé Israẹli lọ́wọ́ ní pípa. Ìwọ yóò já iṣan ẹ̀yìn ẹṣin wọn, ìwọ yóò sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí pé ní ìwòyí ọ̀la, òkú wọn ni n óo fi lé Israẹli lọ́wọ́. Dídá ni kí ẹ dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru nitori wọn: nitori li ọla li akokò yi emi o fi gbogbo wọn tọrẹ niwaju Israeli ni pipa: iwọ o já patì ẹṣin wọn, iwọ o si fi iná sun kẹkẹ́ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:6
24 Iomraidhean Croise  

Dafidi sì gba ẹgbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ẹlẹ́ṣin, àti ẹgbàáwàá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀: Dafidi sì já gbogbo àwọn ẹṣin kẹ̀kẹ́ wọn ní pàtì, ṣùgbọ́n ó dá ọgọ́ọ̀rún kẹ̀kẹ́ sí nínú wọn.


“Má ṣe bẹ̀rù,” wòlíì náà dáhùn, “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa, wọ́n pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.”


Ní ọ̀la, ẹ sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ, wọn yóò gòkè pẹ̀lú, ẹ̀yin yóò sì rí wọn ní ìpẹ̀kun odò náà, níwájú aginjù Jerueli.


Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run. A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè A ó gbé mi ga ní ayé.


Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.


O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná


Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.


Ẹ̀yin wí pé, ‘bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’ Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá! Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’ Nítorí náà àwọn tí ń lé e yín yóò yára!


Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti fún ìrànlọ́wọ́, tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn, ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli n nì, tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa.


“ ‘Nígbà náà, àwọn ti ó ń gbé nì àárín àwọn ìlú tí ó wà ni Israẹli yóò jáde, wọn yóò sì lo àwọn ohun ìjà bi epo ìdáná yóò sì jó wọ́n kanlẹ̀—àpáta kéékèèkéé àti àpáta ńlá, àwọn ọfà, àwọn kùmọ̀ ogun àti ọ̀kọ̀ fún ọdún méje wọn yóò lò wọ́n bi epo ìdáná.


Asiria kò le gbà wá là; A kò ní í gorí ẹṣin ogun A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé ‘Àwọn ni òrìṣà wa sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe; nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú.’


“Kíyèsi i èmi dojúkọ ọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín, idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run. Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé Ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni a kì yóò sì tún gbọ́ mọ́.”


Gbogbo àwọn ènìyàn tí Olúwa Ọlọ́run yín fi lé yín lọ́wọ́ ni kí ẹ parun pátápátá. Ẹ má ṣe ṣàánú fún wọn, ẹ má ṣe sin olúwa ọlọ́run wọn torí pé ìdánwò ni èyí jẹ́ fún un yín.


Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn; Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojúkọ ọ́.”


Gbogbo àwọn ọba yìí pa ọmọ-ogun wọn pọ̀, wọ́n sì pa ibùdó sí ibi omi Meromu láti bá Israẹli jà.


Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ yọ sí wọn ní òjijì ní ibi omi Meromu, wọ́n sì kọlù wọ́n,


Joṣua sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ: Ó sì já iṣan ẹ̀yìn ẹsẹ̀ ẹṣin wọn ó sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.


Joṣua sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́, nítorí ní ọ̀la, Olúwa yóò ṣe ohun ìyanu ní àárín yín.”


Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) Wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Benjamini arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?” Olúwa dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.”


Ní òru ọjọ́ náà Olúwa sọ fún Gideoni pé, “Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Midiani nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́.


Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó wá pé, “Sọ fún àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi pé, ní àkókò tí oòrùn bá mú lọ́la, àwa yóò gbà yín sílẹ̀.” Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà lọ tí wọ́n sì sọ èyí fún àwọn ọkùnrin Jabesi, inú wọn sì dùn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan