Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 10:8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn; Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojúkọ ọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 OLUWA wí fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù wọn, nítorí pé mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní lè ṣẹgun rẹ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru wọn: nitoriti mo ti fi wọn lé ọ lọwọ; ki yio sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 10:8
16 Iomraidhean Croise  

Sì kíyèsi i, wòlíì kan tọ Ahabu ọba Israẹli wá, ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ rí gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun yìí? Èmi yóò fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ lónìí, nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”


Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa?


Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀. kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.”


Yóò fi àwọn ọba wọn lé e yín lọ́wọ́, ẹ̀yin ó sì pa orúkọ wọn rẹ́ lábẹ́ ọ̀run. Kò sí ẹni tí yóò lè dojú ìjà kọ yín títí tí ẹ ó fi pa wọ́n run.


Joṣua sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni Olúwa yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.”


Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́de ogun ní gbogbo òru náà láti Gilgali, Joṣua sì yọ sí wọn lójijì.


Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí ní àkókò yìí ní ọ̀la, gbogbo wọn ni èmi yóò fi lé Israẹli lọ́wọ́ ní pípa. Ìwọ yóò já iṣan ẹ̀yìn ẹṣin wọn, ìwọ yóò sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”


Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù, kí àyà kí ó má ṣe fò ọ́. Kó gbogbo àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ, kí ẹ gòkè lọ gbógun ti Ai. Nítorí mo ti fi ọba Ai, àwọn ènìyàn rẹ̀, ìlú u rẹ̀ àti ilẹ̀ ẹ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.


Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì pa gbogbo àwọn ará Midiani láì ku ẹnìkankan.”


Ní òru ọjọ́ náà Olúwa sọ fún Gideoni pé, “Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Midiani nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́.


Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni Olúwa fi ń gbàlà; ogun náà ti Olúwa ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ wa.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan