Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 10:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gòkè lọ láti Gilgali pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, àti akọni nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Joṣua bá lọ láti Giligali, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju ati akọni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Bẹ̃ni Joṣua gòke lati Gilgali lọ, on ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn alagbara akọni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 10:7
5 Iomraidhean Croise  

“Má ṣe pe èyí ní ọ̀tẹ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn yìí pè ní ọ̀tẹ̀, má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù, má sì ṣe fòyà rẹ̀.


Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́ ṣùgbọ́n fún ilé Israẹli méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọsẹ̀ àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú àti fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni yóò jẹ́ tàkúté àti ìdẹ̀kùn.


Àwọn ará Gibeoni sì ránṣẹ́ sí Joṣua ní ibùdó ní Gilgali pé: “Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín sílẹ̀. Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là. Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Amori tí ń gbé ní orílẹ̀-èdè òkè dojú ìjà kọ wá.”


Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù, kí àyà kí ó má ṣe fò ọ́. Kó gbogbo àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ, kí ẹ gòkè lọ gbógun ti Ai. Nítorí mo ti fi ọba Ai, àwọn ènìyàn rẹ̀, ìlú u rẹ̀ àti ilẹ̀ ẹ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.


Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun jáde lọ láti dojúkọ Ai. Ó sì yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àwọn ọkùnrin ogun rẹ̀ ti ó yakin, ó sì rán wọn lọ ní òru.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan