Joṣua 10:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní6 Àwọn ará Gibeoni sì ránṣẹ́ sí Joṣua ní ibùdó ní Gilgali pé: “Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín sílẹ̀. Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là. Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Amori tí ń gbé ní orílẹ̀-èdè òkè dojú ìjà kọ wá.” Faic an caibideilYoruba Bible6 Àwọn ará Gibeoni bá ranṣẹ sí Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Giligali. Wọ́n ní, “Ẹ má fi àwa iranṣẹ yín sílẹ̀! Ẹ tètè yára wá gbà wá kalẹ̀, ẹ wá ràn wá lọ́wọ́. Nítorí pé, gbogbo àwọn ọba Amori, tí wọn ń gbé agbègbè olókè, ti kó ara wọn jọ sí wa.” Faic an caibideilBibeli Mimọ6 Awọn ọkunrin Gibeoni si ranṣẹ si Joṣua ni ibudó ni Gilgali, wipe, Má ṣe fà ọwọ́ rẹ sẹhin kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ; gòke tọ̀ wa wá kánkán, ki o si gbà wa, ki o si ràn wa lọwọ: nitoriti gbogbo awọn ọba Amori ti ngbé ori òke kójọ pọ̀ si wa. Faic an caibideil |