Joṣua 10:1 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Ní báyìí tí Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu gbọ́ pé Joṣua ti gba Ai, tí ó sì ti pa wọ́n pátápátá; tí ó sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gibeoni ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Israẹli, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn. Faic an caibideilYoruba Bible1 Nígbà tí Adonisedeki, ọba Jerusalẹmu, gbọ́ bí Joṣua ṣe gba ìlú Ai, ati pé ó pa ìlú Ai ati ọba rẹ̀ run, bí ó ti ṣe sí ìlú Jẹriko ati ọba rẹ̀; ati pé àwọn ará Gibeoni ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia, wọ́n sì ń gbé ààrin wọn, Faic an caibideilBibeli Mimọ1 O SI ṣe, nigbati Adoni-sedeki ọba Jerusalemu gbọ́ pe Joṣua ti kó Ai, ti o si pa a run patapata; bi o ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀, bẹ̃li o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀; ati bi awọn ara Gibeoni ti bá Israeli ṣọrẹ, ti nwọn si ngbé ãrin wọn; Faic an caibideil |