Joṣua 1:7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, Má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ. Faic an caibideilYoruba Bible7 Ìwọ ṣá ti múra, kí o ṣe ọkàn gírí, kí o sì rí i dájú pé o pa gbogbo òfin tí Mose, iranṣẹ mi, fún ọ mọ́. Má ṣe yẹsẹ̀ kúrò ninu rẹ̀ sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé níbikíbi tí o bá lọ lè máa yọrí sí rere. Faic an caibideilBibeli Mimọ7 Sá ṣe giri ki o si mu àiya le gidigidi, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi ti palaṣẹ fun ọ: má ṣe yà kuro ninu rẹ̀ si ọtún tabi si òsi, ki o le dara fun ọ nibikibi ti iwọ ba lọ. Faic an caibideil |