Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 9:32 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

32 Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

32 Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé a kò rí i gbọ́ pé ẹnikẹ́ni la ojú ẹni tí wọ́n bí ní afọ́jú rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

32 Lati igba ti aiye ti ṣẹ̀, a kò ti igbọ́ pe, ẹnikan là oju ẹniti a bí li afọju rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 9:32
7 Iomraidhean Croise  

“Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́, láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ sílé ayé,


Láti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ, kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.


(bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́),


Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mí èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?”


Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀.


Ìbá ṣe pé ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kì bá tí lè ṣe ohunkóhun.”


Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò ṣẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tó bẹ́ẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan