Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 9:10 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Bá wo ni ojú rẹ ṣe là?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Wọ́n bi í pé, “Báwo ni ojú rẹ́ ti ṣe là?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Nitorina ni nwọn wi fun u pe, Njẹ oju rẹ ti ṣe là?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 9:10
11 Iomraidhean Croise  

Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.


Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Baruku pé, “Sọ fún wa báwo ni o ṣe kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ṣé Jeremiah ló sọ wọ́n?”


Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìde, irúgbìn náà hu jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀.


Nikodemu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Nǹkan wọ̀nyí yóò ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”


Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu kọjá sí apá kejì Òkun Galili, tí í ṣe Òkun Tiberia.


Ó dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jesu ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kun ojú mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Lọ sí adágún Siloamu, kí o sì wẹ̀,’ èmi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.”


Nítorí náà àwọn Farisi pẹ̀lú tún bi í léèrè, bí ó ti ṣe ríran. Ọkùnrin náà fèsì, “Ó fi amọ̀ lé ojú mi, mo sì wẹ̀, báyìí mo sì ríran.”


Ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe ń ríran nísinsin yìí àwa kò mọ̀; ẹni tí ó là á lójú, àwa kò mọ̀: ẹni tí ó ti dàgbà ni òun; ẹ bi í léèrè: yóò wí fúnrarẹ̀.”


Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé, “Kí ni ó ṣe ọ́? Báwo ni ó ṣe là ọ́ lójú.”


Àwọn kan wí pé òun ni. Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ó jọ ọ́ ni.” Ṣùgbọ́n òun wí pé, “Èmi ni.”


Ṣùgbọ́n ẹnìkan yóò wí pé, “Báwo ni àwọn òkú yóò ṣe jíǹde? Irú ara wó ni wọn ó padà sí?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan