Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:49 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

49 Jesu sì dáhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù, ṣùgbọ́n èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ẹ̀yin kò sì bu ọlá fún mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

49 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù rárá! Èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ṣugbọn ẹ̀yin ń bu ẹ̀tẹ́ lù mí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

49 Jesu dahùn wipe, Emi kò li ẹmi èṣu; ṣugbọn emi mbọlá fun Baba mi, ẹnyin kò si bọla fun mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:49
16 Iomraidhean Croise  

Ó dùn mọ́ Olúwa nítorí òdodo rẹ̀ láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo.


Ó sọ fún mi pé, “ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe, Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.”


Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún Ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.”


Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo!” Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, “Èmi ti ṣe é lógo!”


Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, òun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ.


Èmi ti yìn ọ́ lógo ní ayé: èmi ti parí iṣẹ́ tí ìwọ fi fún mi láti ṣe.


Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èṣù: Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”


Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.”


Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀.


Ǹjẹ́ ìwà abínibí yín kò ha kọ́ yín pé, bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un.


A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo; a gbìn ín ni àìlera, a sì jí í dìde ní agbára.


Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan