Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:43 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

43 Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

43 Nítorí kí ni ohun tí mò ń sọ fun yín kò fi ye yín? Ìdí rẹ̀ ni pé ara yín kò lè gba ọ̀rọ̀ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

43 Ẽtiṣe ti ède mi kò fi yé nyin? nitori ẹ ko le gbọ́ ọ̀rọ mi ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:43
18 Iomraidhean Croise  

Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá Olúwa dáradára.


Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn; a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan; bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan.


Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé: “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’


Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́. Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn, wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.


Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn. Títọ́ ni ọ̀nà Olúwa àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.


Ṣùgbọ́n wọn kò mọ èrò inú Olúwa; Bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà.


Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́ etí wọn sì wúwo láti gbọ́ ojú wọn ni wọ́n sì dì nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí kí wọ́n má ba à fi etí wọn gbọ́ kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òye, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi ba à le mú wọn láradá.’


Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn ọmọ Ọlọ́run: àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè.


Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò sì gbà mí; bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, òun ni ẹ̀yin yóò gbà.


Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Ọ̀rọ̀ tí ó le ni èyí; ta ní lè gbọ́ ọ?”


Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bí ìbá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi.


Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn.


Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-ọmọ Abrahamu ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?”


Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Abrahamu ni baba wa!” Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Abrahamu


“Ẹ̀yin ọlọ́rùn líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yin rí: Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́!


Kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan