Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:34 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

34 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

34 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

34 Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:34
16 Iomraidhean Croise  

(Kò sí ẹnìkan bí Ahabu tí ó ta ara rẹ̀ láti ṣe búburú níwájú Olúwa, ẹni tí Jesebeli aya rẹ̀ ń tì.


Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn; okùn ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ yóò sì dìímú.


Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, ààmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ.


Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a tún ènìyàn bí, òun kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.”


Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹró ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.”


Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.


Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́? Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ ti o yọrí si ikú tàbí ìgbọ́ràn ti o yọrí sí ìdáláre. Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fi ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀.


Gbogbo èrò búburú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.


Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin: ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.


Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa! Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi fúnra mi jẹ́ ẹrú sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.


Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkára rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdíbàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run.


nínú èyí tí ẹ̀yin ti gbé rí, àní bí ìlànà ti ayé yìí, gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ agbára ojú ọ̀run, ẹ̀mí tí n ṣiṣẹ́ ni ìsinsin yìí nínú àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn.


Nígbà kan rí, àwa pàápàá jẹ́ òpè àti aláìgbọ́ràn, àti tàn wá jẹ, a sì ti sọ wá di ẹrú fún onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti adùn ayé. À ń gbé ìgbé ayé àrankàn àti owú kíkorò, a jẹ́ ẹni ìríra, a sì ń kórìíra ọmọ ẹnìkejì wa pẹ̀lú.


Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọ̀gá rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan