Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:21 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ ní tèmi; ẹ óo máa wá mi kiri, ẹ óo sì kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Nitorina o tun wi fun wọn pe, Emi nlọ, ẹnyin yio si wá mi, ẹ ó si kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: ibiti emi gbe nlọ, ẹnyin kì ó le wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:21
21 Iomraidhean Croise  

Mo mọ̀ dájú pé bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ, kò sí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan tí olúwa mi kò ti rán ènìyàn lọ láti wò ọ́. Àti nígbà tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan bá wí pé o kò sí, òun a sì mú kí wọ́n búra wí pé wọn kò rí ọ.


Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀, tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.


Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo.


Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀, kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.


“Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀, tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán; ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé; ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan ni a ó pè ní ẹni ìfibú.


Nítorí èmi sọ èyí fún yín, ẹ̀yin kì yóò rí mi mọ́, títí ẹ̀yin yóò fi sọ pé ‘Olùbùkún ni ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa.’ ”


“Nígbà náà ni yóò sọ fún àwọn tí ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti tọ́jú fún èṣù àti àwọn angẹli rẹ̀.


“Nígbà náà wọn yóò sì kọjá lọ sínú ìyà àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.”


Ṣùgbọ́n ó wí èyí, ó ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.


Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà díẹ̀ sí i ni ìmọ́lẹ̀ wà láàrín yín, ẹ máa rìn nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má ṣe bá yín: ẹni tí ó bá sì ń rìn ní òkùnkùn kò mọ ibi òun ń lọ.


“Ẹ̀yin ọmọ mi, nígbà díẹ̀ sí i ni èmi wà pẹ̀lú yín. Ẹ̀yin yóò wá mi: àti gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún àwọn Júù pé, Níbi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò le wà; bẹ́ẹ̀ ni mo sì wí fún yín nísinsin yìí.


Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”


Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà?”


Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.”


Ní ti ẹ̀yin, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè, nígbà ti ẹ̀yin ti kú nítorí ìrékọjá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan