Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Nítorí náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Àkókò gan an fún mi kò tí ì dé; fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò tí ó wọ̀ fún mi kò ì tíì tó, ìgbà gbogbo ni ó wọ̀ fún ẹ̀yin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Akokò temi kò ti ide: ṣugbọn akokò ti nyin ni imura tan nigbagbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:6
10 Iomraidhean Croise  

Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni, nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i; àkókò náà ti dé.


Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé: Àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ”


Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jesu mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin.


Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ó sì wí pé: “Baba, wákàtí náà dé, yin ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ kí ó lè yìn ọ́ lógo pẹ̀lú.


Jesu fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èéṣe tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.”


Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà à ti mú un: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.


Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí: èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí; nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé.”


Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jesu sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹmpili: ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.


Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe tiyín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkára rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan