Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:42 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

42 Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

42 Ṣebí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé láti inú ìdílé Dafidi, ní Bẹtilẹhẹmu ìlú Dafidi, ni Mesaya yóo ti wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

42 Iwe-mimọ́ kò ha wipe, Kristi yio ti inu irú ọmọ Dafidi wá, ati Betlehemu, ilu ti Dafidi ti wà?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:42
17 Iomraidhean Croise  

Salma baba Bẹtilẹhẹmu àti Harefu baba Beti-Gaderi.


Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi: Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.


‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”


Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese, láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso.


“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi, ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.


“Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata, bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda, nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹli yóò ti jáde tọ̀ mí wá, ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́, láti ìgbà láéláé.”


Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu:


Wọ́n sì wí pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé:


“ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judea, ìwọ kò kéré jù láàrín àwọn ọmọ-aládé Juda; nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde, Ẹni ti yóò ṣe ìtọ́jú Israẹli, àwọn ènìyàn mi.’ ”


Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa.


Josẹfu pẹ̀lú sì gòkè láti Nasareti ni Galili, sí ìlú Dafidi ní Judea, tí à ń pè ní Bẹtilẹhẹmu; nítorí ti ìran àti ìdílé Dafidi ní í ṣe,


Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá: ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”


Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa dárò Saulu, nígbà tí ó jẹ́ pé mo ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Israẹli? Rọ òróró kún inú ìwo rẹ, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, Èmi rán ọ sí Jese ará Bẹtilẹhẹmu. Èmi ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ ọba.”


Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, “Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jese ti Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun. Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò. Olúwa sì wà pẹ̀lú u rẹ̀.”


Samuẹli ṣe ohun tí Olúwa sọ. Nígbà tí ó dé Bẹtilẹhẹmu, àyà gbogbo àgbàgbà ìlú já, nígbà tí wọ́n pàdé rẹ̀. Wọ́n béèrè pé, “Ṣé àlàáfíà ní ìwọ bá wá?”


Saulu béèrè pé, “Ọmọdékùnrin, ọmọ ta ni ọ́?” Dafidi dáhùn pé, “Èmi ni ọmọ ìránṣẹ́ rẹ Jese ti Bẹtilẹhẹmu.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan