Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:14 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 Nígbà tí àjọ dé àárín; Jesu gòkè lọ sí tẹmpili ó sì ń kọ́ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

14 Nígbà tí àjọ̀dún ti fẹ́rẹ̀ kọjá ìdajì, Jesu lọ sí Tẹmpili, ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

14 Nigbati ajọ de arin Jesu gòke lọ si tẹmpili o si nkọ́ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:14
16 Iomraidhean Croise  

“Wò ó, Èmi yóò ran ìránṣẹ́ mi, yóò tún ọ̀nà ṣe ṣáájú mi. Nígbà náà ni Olúwa, tí ẹ̀yin ń wa, yóò dé ni òjijì sí tẹmpili rẹ̀; àní oníṣẹ́ májẹ̀mú náà, tí inú yín dùn sí, yóò dé,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.


“ ‘Àti ní ọjọ́ kejì ni kí ẹ̀yin kí ó fi ẹgbọrọ akọ màlúù méjìlá, àgbò méjì àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ọlọ́dún kan aláìlábùkù rú ẹbọ.


“ ‘Ní ọjọ́ kẹta, pèsè akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì, akọ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọdún kan tí kò ní àbùkù.


Jesu sì wọ inú tẹmpili, Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn tí ń rà níbẹ̀ jáde. Ó yí tábìlì àwọn onípàṣípàrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlé.


Nígbà náà ni Jesu wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Ǹjẹ́ èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹmpili, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà.


Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á.


Jesu dá a lóhùn pé, “Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sinagọgu, àti ní tẹmpili níbi tí gbogbo àwọn Júù ń péjọ sí: èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀.


Lẹ́yìn náà, Jesu rí i nínú tẹmpili ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!”


Àjọ àwọn Júù tí í ṣe àjọ àgọ́ súnmọ́ etílé tan.


Nígbà náà ni Jesu kígbe ní tẹmpili bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá: èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀.


Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu.


Ó sì tún padà wá sí tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn.


Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jesu sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹmpili: ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan