Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:13 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Ṣugbọn wọn kò sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Ṣugbọn kò si ẹnikan ti o sọ̀rọ rẹ̀ ni gbangba nitori ìbẹru awọn Ju.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:13
13 Iomraidhean Croise  

Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.


Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Josẹfu ará Arimatea, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pilatu kí òun lè gbé òkú Jesu kúrò: Pilatu sì fún un ní àṣẹ. Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jesu lọ.


Ní ọjọ́ kan náà, lọ́jọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jesu dé, ó dúró láàrín, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.”


Òun náà ní ó tọ Jesu wá ní òru, ó sì wí fún un pé, Rabbi, àwa mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ìwọ ń ṣe: nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ ààmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe, bí kò ṣe pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.


Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jesu ń rìn ní Galili: nítorí tí kò fẹ́ rìn ní Judea, nítorí àwọn Júù ń wá a láti pa.


Nígbà náà ni àwọn Júù sì ń wá a kiri nígbà àjọ wí pé, “Níbo ni ó wà?”


Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́?”


Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn òbí rẹ̀ sọ, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù àwọn Júù: nítorí àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan pé bí ẹnìkan bá jẹ́wọ́ pé Kristi ni, wọn ó yọ ọ́ kúrò nínú Sinagọgu.


Sí èyí, wọ́n fèsì pé: “Láti ìbí ni o tì jíngírí nínú ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ ha fẹ́ kọ́ wa bí?” Wọ́n sì tì í sóde.


Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Satani wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Antipa ẹlẹ́rìí mi, olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrín yín, níbi tí Satani ń gbé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan