Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 6:71 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

71 (Ó ń sọ ti Judasi Iskariotu ọmọ Simoni ọ̀kan nínú àwọn méjìlá: nítorí pé òun ni ẹni tí yóò fi í hàn.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

71 Ó wí èyí nípa Judasi Iskariotu ọmọ Simoni, nítorí òun ni ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ni Judasi Iskariotu yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

71 O nsọ ti Judasi Iskariotu ọmọ Simoni: nitoripe on li ẹniti yio fi i hàn, ọkan ninu awọn mejila.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 6:71
19 Iomraidhean Croise  

Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi, tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.


Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí: ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu; Jakọbu ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu.


Simoni ọmọ ẹgbẹ́ Sealoti, Judasi Iskariotu, ẹni tí ó da Jesu.


Nígbà náà ni Judasi Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, láti ṣètò bí yóò ti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.


Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé,


Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn;


Nítorí náà Jesu dáhùn pé, “Òun náà ni, ẹni tí mo bá fi àkàrà fún nígbà tí mo bá fi run àwo.” Nígbà tí ó sì fi run ún tan, ó fi fún Judasi Iskariotu ọmọ Simoni.


A sì pe Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà.


Ṣùgbọ́n Tomasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Didimu, kò wà pẹ̀lú wọn nígbà tí Jesu dé.


Ṣùgbọ́n àwọn kan wà nínú yín tí kò gbàgbọ́.” Nítorí Jesu mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ẹni tí wọ́n jẹ́ tí kò gbàgbọ́, àti ẹni tí yóò fi òun hàn.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin méjìlá kọ́ ni mo yàn, ọ̀kan nínú yín kò ha sì ya èṣù?”


Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú kàn mọ́ àgbélébùú, tí a sì pa á.


Nítorí àwọn ènìyàn kan ń bẹ tí wọ́n ń yọ́ wọlé, àwọn ẹni tí a ti yàn láti ìgbà àtijọ́ sí ẹ̀bi yìí, àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ń yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wa padà sí wọ̀bìà, tí wọn sì ń sẹ́ Olúwa wa kan ṣoṣo náà, àní, Jesu Kristi Olúwa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan