Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 6:22 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Ní ọjọ́ kejì nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó dúró ní òdìkejì Òkun rí i pé, kò sí ọkọ̀ ojú omi mìíràn níbẹ̀, bí kò ṣe ọ̀kan náà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ̀, àti pé Jesu kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi náà, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni ó lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

22 Ní ọjọ́ keji, àwọn tí wọ́n dúró ní òdìkejì òkun rí i pé ọkọ̀ kanṣoṣo ni ó wà níbẹ̀. Wọ́n tún wòye pé Jesu kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni wọ́n lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Ni ijọ keji, nigbati awọn enia ti o duro li apakeji okun ri pe, kò si ọkọ̀ miran nibẹ̀, bikoṣe ọkanna ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀, ati pe Jesu kò ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wọ̀ inu ọkọ̀ na, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nikan li o lọ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 6:22
4 Iomraidhean Croise  

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdìkejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn


Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti padà sínú ọkọ̀ kí wọn sì ṣáájú rékọjá sí Betisaida. Níbẹ̀ ni òun yóò ti wà pẹ̀lú wọn láìpẹ́. Nítorí òun fúnra a rẹ̀ yóò dúró sẹ́yìn láti rí i pé àwọn ènìyàn túká lọ ilé wọn.


Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan