Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Bí Jesu ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Nígbà tí Jesu rí i tí ó dùbúlẹ̀ níbẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tí ó ti wà níbẹ̀, ó bi í pé, “Ṣé o fẹ́ ìmúláradá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Bi Jesu ti ri i ni idubulẹ, ti o si mọ̀ pe, o pẹ ti o ti wà bẹ̃, o wi fun u pe, Iwọ fẹ ki a mu ọ larada bi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:6
9 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi. Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀


“Èmi fi ara mi hàn fún àwọn tí kò béèrè fún mi; Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi. Sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò pe orúkọ mi, Ni èmi wí pé, ‘Èmi nìyìí, Èmi nìyìí.’


ìwà àgbèrè àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àìlójútì panṣágà rẹ! Mo ti rí ìwà ìríra rẹ, lórí òkè àti ní pápá. Ègbé ni fún ọ ìwọ Jerusalẹmu! Yóò ti pẹ́ tó tí o ó fi máa wà ní àìmọ́?”


Wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?” Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”


Ó wí fún un nígbà kẹta pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?” Inú Peteru sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹta pé, “Ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.


Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjì-dínlógójì.


Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, “Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà: bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ síwájú mi.”


Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòhò tí a sì ṣípáyà fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn.


Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì ba ni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́ṣẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan