Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjì-dínlógójì.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ó ti ń ṣàìsàn fún ọdún mejidinlogoji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ọkunrin kan si wà nibẹ̀, ẹniti o wà ni ailera rẹ̀ li ọdún mejidilogoji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:5
12 Iomraidhean Croise  

Jesu béèrè lọ́wọ́ baba ọmọ náà pé, “Ó tó ìgbà wo tí ọmọ rẹ̀ ti wà nínú irú ipò báyìí?” Baba ọmọ náà dáhùn pé, “Láti kékeré ni.”


Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjì-dínlógún yìí wá?”


Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá,


Lẹ́yìn náà, Jesu rí i nínú tẹmpili ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!”


Nítorí angẹli a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú adágún náà, a sì máa rú omi rẹ̀: lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti rú omi náà tan ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ wọ inú rẹ̀ a di alára dídá kúrò nínú ààrùnkárùn tí ó ní.


Bí Jesu ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”


Bí ó sì ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí rẹ̀ wá.


Ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe ń ríran nísinsin yìí àwa kò mọ̀; ẹni tí ó là á lójú, àwa kò mọ̀: ẹni tí ó ti dàgbà ni òun; ẹ bi í léèrè: yóò wí fúnrarẹ̀.”


Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lysra, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí.


Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹmpili lọ,


Nítorí ọkùnrin náà lára ẹni tí a ṣe iṣẹ́ ààmì ìmúláradá, ju ẹni ogójì ọdún lọ.


Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Aenea tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní ààrùn ẹ̀gbà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan