Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 5:17 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

17 Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

17 Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

17 Ṣugbọn Jesu da wọn lohùn wipe, Baba mi nṣiṣẹ titi di isisiyi, emi si nṣiṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 5:17
15 Iomraidhean Croise  

Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ, tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára


Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run: Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí? Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan. Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀, ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù.


Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin.


Kín ni ẹyin ha ń wí ní ti ẹni tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó sì rán sí ayé kín lo de ti ẹ fi ẹ̀sùn kàn mi pé mò ń sọ̀rọ̀-òdì nítorí pé mo sọ pé, ‘Èmi ni ọmọ Ọlọ́run.’


Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.


Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jesu, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí o ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi.


Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba.


Èmi ní láti ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ ọ̀sán: òru ń bọ̀ wá nígbà tí ẹnìkan kì yóò lè ṣe iṣẹ́.


Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti ni àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.”


Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láààyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa: bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkára yín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’


Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣiṣẹ́ gbogbo wọn nínú gbogbo wọn.


Nítorí nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un.


Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.


Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan