Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:47 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti Judea wá sí Galili, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti dé sí Galili láti Judia, ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá wo ọmọ òun sàn, nítorí ọmọ ọ̀hún ń kú lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

47 Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Judea wá si Galili, o tọ̀ ọ wá, o si mbẹ̀ ẹ, ki o le sọkalẹ wá ki o mu ọmọ on larada: nitoriti o wà li oju ikú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:47
12 Iomraidhean Croise  

Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.


Lẹ́yìn ìgbà tí a bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, ni àkókò ọba Herodu, àwọn amòye ti ìlà-oòrùn wá sí Jerusalẹmu.


Nígbà tí Bartimeu gbọ́ pé Jesu ti Nasareti wà nítòsí, o bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi.”


Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jairu, ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu wá; ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó wá sí ilé òun:


Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.


Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.”


Ó fi Judea sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Galili.


Èyí ni iṣẹ́ ààmì kejì tí Jesu ṣe nígbà tí ó ti Judea jáde wá sí Galili.


Bí Lida sì ti súnmọ́ Joppa, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ pé Peteru wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, “Má ṣe jáfara láti dé ọ̀dọ̀ wa.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan