Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:32 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

32 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní oúnjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

32 Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Mo ní oúnjẹ láti jẹ tí ẹ̀yin kò mọ̀ nípa rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

32 Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Emi li onjẹ lati jẹ, ti ẹnyin kò mọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:32
13 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀, èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.


Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó, ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!


Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀; ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.


A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ; pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.


Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀ kò sì ṣí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.


Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó; láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.


Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.


Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n Àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi Nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.


Láàrín èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Rabbi, jẹun.”


Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnìkan mú oúnjẹ fún un wá láti jẹ bí?”


Jesu wí fún wọn pé, “Oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.


Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’  ”


Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ; Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi manna tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan