Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:28 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

28 Nígbà náà ni obìnrin náà fi ládugbó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú, ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

28 Obinrin náà fi ìkòkò omi rẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sí ààrin ìlú, ó sọ fún àwọn eniyan pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

28 Nigbana li obinrin na fi ladugbo rẹ̀ silẹ, o si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n lọ si ilu, o si wi fun awọn enia pe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:28
8 Iomraidhean Croise  

Naamani lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Israẹli ti sọ.


Àwọn obìnrin náà sáré kúrò ní ibojì pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá. Wọ́n sáré láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nípa ìròyìn tí angẹli náà fi fún wọn.


Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn,


Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù.


Lákokò yí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?”


“Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi: èyí ha lè jẹ́ Kristi náà?”


Obìnrin kan, ará Samaria sì wá láti fà omi: Jesu wí fún un pé ṣe ìwọ yóò fún mi ni omi mu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan