Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:24 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

24 Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

24 Ẹ̀mí ni Ọlọrun, àwọn tí ó bá ń sìn ín níláti sìn ín ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

24 Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:24
13 Iomraidhean Croise  

Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.


Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe, kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”


Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.


Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi, Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;


Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́: “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.


Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun.


Nítorí èyí ní ìṣògo wá, ẹ̀rí láti inú ọkàn wa pẹ̀lú si jẹ́rìí wí pé àwa ń gbé ìgbésí ayé tí ó ní ìtumọ̀ pàápàá jùlọ nínú ìbágbépọ̀ wa pẹ̀lú yín, nínú ìwà mímọ́ àti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Kì í ṣe nípa ọgbọ́n ti ara ni àwa ń ṣe èyí bí kò ṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.


Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà


Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kristi Jesu, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran-ara.


Ǹjẹ́ fún ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé. Àmín.


Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Olúwa kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n Olúwa máa ń wo ọkàn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan