Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:29 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

29 Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

29 Ọkọ iyawo ni ó ni iyawo, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo, tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, á máa láyọ̀ láti gbọ́ ohùn ọkọ iyawo. Nítorí náà ayọ̀ mi yìí di ayọ̀ kíkún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

29 Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:29
27 Iomraidhean Croise  

Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni, kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé, adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.


Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; mo ti kó òjìá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ. Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi; mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi. Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu, àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́.


Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ; a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.


Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára; Ẹ̀yin yóò mu àmuyó ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”


“Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé: “Báyìí ni Olúwa wí, “ ‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ, ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹ àti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù, nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.


“ ‘Nígbà tí mo tún kọjá, tí mo rí ọ, mo rí i pé àsìkò àti nífẹ̀ẹ́ rẹ ti tó, mo fi ìṣẹ́tí aṣọ mi bo ìhòhò rẹ. Mo búra fún ọ, èmi sì bá ọ dá májẹ̀mú ìwọ sì di tèmi, ni Olúwa Olódùmarè wí.


Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé. Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú.


“Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan ti ó múra àsè ìgbéyàwó ńlá fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin.


“Nígbà náà ni ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúńdíá mẹ́wàá. Ti wọ́n gbé fìtílà wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó.


Jesu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa ṣọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀.


Nígbà tí ó bá sì dé ilé yóò pe àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóò sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mí yọ̀; nítorí tí mo ti rí àgùntàn mi tí ó nù.’


Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí ayọ̀ mi kí ó lè wà nínú yín, àti kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.


Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi: ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.


“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn.


Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹlẹ̀.


Nítorí pé èmi ń jowú lórí i yín bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run: nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúńdíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kristi.


síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìṣọ̀kan yín, nípa ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà.


Àwa sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ayọ̀ yín kí ó lè di kíkún.


Bí mo tilẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alábápín pẹ̀lú yín, síbẹ̀ èmi kò fẹ́ lo ìwé ìkọ̀wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.


Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje, tí wọ́n ni ago méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-àgùntàn hàn ọ́.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan