Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:28 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

28 Ẹ̀yin fúnrayín jẹ́rìí mi pé mo wí pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi síwájú rẹ̀.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

28 Ẹ̀yin fúnra yín jẹ́rìí mi pé mo sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣugbọn èmi ni a rán ṣiwaju rẹ̀.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

28 Ẹnyin tikaranyin jẹri mi, pe mo wipe, Emi kì iṣe Kristi na, ṣugbọn pe a rán mi ṣiwaju rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:28
12 Iomraidhean Croise  

“Wò ó, Èmi yóò ran ìránṣẹ́ mi, yóò tún ọ̀nà ṣe ṣáájú mi. Nígbà náà ni Olúwa, tí ẹ̀yin ń wa, yóò dé ni òjijì sí tẹmpili rẹ̀; àní oníṣẹ́ májẹ̀mú náà, tí inú yín dùn sí, yóò dé,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.


Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Isaiah sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ohùn ẹni ti ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”


“Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́: nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;


Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, “Èmi kì í ṣe Kristi náà.”


Johanu sì fi ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah fún wọn ní èsì pé, “Èmi ni ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà Olúwa ní títọ́.’ ”


bi í léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bamitiisi nígbà náà, bí ìwọ kì í bá ṣe Kristi, tàbí Elijah, tàbí wòlíì náà?”


Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan