Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:23 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Johanu pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Aenoni, ní agbègbè Salimu, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀: wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọ omi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

23 Johanu náà ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan ní Anoni lẹ́bàá Salẹmu, nítorí omi pọ̀ níbẹ̀. Àwọn eniyan ń wọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

23 Johanu pẹlu si mbaptisi ni Ainoni, li àgbegbe Salimu, nitoriti omi pipọ wà nibẹ̀: nwọn si nwá, a si baptisi wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:23
13 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu tí Padani-Aramu dé: Àlàáfíà ni Jakọbu dé ìlú Ṣekemu ní ilẹ̀ Kenaani, ó sì pàgọ́ sí itòsí ìlú náà.


Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀, tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé, àní àsìkò láti ké ọ kúrò!


“ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀; tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso, ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi,


mo sì ri ògo Ọlọ́run Israẹli ń bọ láti ìhà ìlà-oòrùn. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi, ìtànṣán ògo rẹ̀ sì bo ilẹ̀.


Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?


Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Judea; ó sì dúró pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ni.


Nítorí tí a kò tí ì sọ Johanu sínú túbú.


Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀.


Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí ariwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá: mo sì gbọ́ àwọn aludùùrù tí wọn ń lu dùùrù.


Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé: “Haleluya! Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.


Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrín àwọn ìlú olókè Efraimu, ó sì kọjá ní àyíká ilẹ̀ Ṣaliṣa, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn. Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Ṣaalimu, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀. Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Benjamini, wọn kò sì rí wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan