Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 21:25 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun mìíràn pẹ̀lú ni Jesu ṣe, èyí tí bí a bá kọ̀wé wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé gbogbo ayé pàápàá kò lè gba ìwé náà tí a bá kọ ọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

25 Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni Jesu ṣe, bí a bá kọ wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé kò ní sí ààyè tó ní gbogbo ayé tí yóo gba ìwé tí a bá kọ wọ́n sí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

25 Ọpọlọpọ ohun miran pẹlu ni Jesu ṣe, eyiti bi a ba kọwe wọn li ọkọ̃kan, mo rò pe aiye pãpã kò le gbà iwe na ti a ba kọ. Amin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 21:25
12 Iomraidhean Croise  

Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀; ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó! Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”


Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe. Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa; ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn, wọ́n ju ohun tí ènìyàn le è kà lọ.


Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ, ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́, lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.


Àti síwájú láti inú èyí, Ọmọ mi, gba ìmọ̀ràn. Nínú ìwé púpọ̀, òpin kò sí, ìwé kíkà púpọ̀ a máa mú ara ṣàárẹ̀.


Nígbà náà Amasiah àlùfáà Beteli ránṣẹ́ sí Jeroboamu ọba Israẹli, wí pé: “Amosi ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárín gbùngbùn Israẹli. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.


Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì.


Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”


Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mìí àìmọ́, wọ́n si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú.


Àní Jesu ti Nasareti, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti da Ẹ̀mí Mímọ́ àti agbára le lórí; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.


Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’  ”


Èwo ni èmi o sì tún máa wí sí i? Nítorí pé ìgbà yóò kùnà fún mi láti sọ ti Gideoni, àti Baraki, àti Samsoni, àti Jefta; àti Dafidi, àti Samuẹli, àti ti àwọn wòlíì:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan